John 18:25-27

Peteru sẹ́ Jesu ní ìgbà kejì àti ìgbà kẹta

25 aṢùgbọ́n Simoni Peteru dúró, ó sì ń yáná. Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Ìwọ pẹ̀lú ha jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀?”

Ó sì sẹ́, wí pé, “Èmi kọ́.”

26Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, tí ó jẹ́ ìbátan ẹni tí Peteru gé etí rẹ̀ sọnù, wí pé, “Èmi ko ha rí ọ pẹ̀lú rẹ̀ ní àgbàlá?” 27Peteru tún sẹ́: lójúkan náà àkùkọ sì kọ.

Copyright information for YorBMYO